atoke akewi mr fly chant şarkı sözleri
Afefe lele oooo
Wa gbo ohun mi r'okunnn ooo
Efufu lele
Oya wa gbo ohun mi r'osa
Odi Ile enikan mi
Ile ololade o
Omo bolarinwa shebi iwo ni n pe un
Oko nana shebi iwo ni n pe un
Oko omotunde shebi iwo ni n pe un
Oko aishatu amobiojo ooo
Eleyinju ege oo
Aponbepore arewa l'obinrin
Baba folarin o
Baba folarin o
Mr fly
Me bi eyan o ni mo ru e
Ko tun mo oshi mo ni'le aye
Omo ibadan ni'le oluyole amo ajorosun
O ri, me bi ibe ni se Ile awon baba re
Omo agbosasa ogun ma she sa
E so pele omo agboyaya ma she ya
Eegun lo di mefa lopin ile
Olowo ori nana e mi ni se t'obinrin o m'awo
Paka lo di mefa ni igbaale
Emi ni se t'obinrin o m'awo ololade
Eku lo di mefa mo lo gbo gbo
Nile baba to bi yin lo mo
Omo ologun o di kere ooo
Omo asabari o ko ja
Omo arolu owo o
Arolu ola o
Dogbonyoke esa ogbin ara ogbojo lo l'eyin
Dogbonyoke omo oni'ke re
Omo ike mi o jo t'oya
Ema she gbe mi fun oya
Kashif, kongbe eyin mi o jo to oosha
Ema she gbe mi fun oosha lawe
Ibadan dakan lukan
Bere loju ogun
Ilu ogunmola oooo
Olodongbo keri loju ogun
O bo shokoto kenbe re bi ija
Omo ifa abarapa
Ifa abara kewukewu oo
Ifa abara mi yoyo
Ibadan e i ba ni s'ore ai muni lo s'oju ogun
Iyen ninu Ile awon baba eyin
Mr fly o
Baba folarin
Olowo ori anike un o mo s'aponle re
Omo olooye moyin ajibokin
Eyin l'oke mo le oyo te mu iru ekun ni shonsho ori
Omo aso'ye tan
Ke e to so'ru baba eyin ni
Iji alugbooooo
Ta a ran lo'bi lo'ja
To fi gbogbo owo ke'ni
Eleeni n ka'wo
Olobi n so
Olobi ma so mo
Ibi owo n gbe wa
L'owo n gbe lo
Iyen ninu Ile awon baba eyin
Oke mo le oyo te e gbaru ekun mu ni shonsho ori
Ikii mi leeje
Folajuwon o, ikii mi leefa
Mooopomopo mi lerin din l'ogun o
Iji olele oye dun marookun
Iji olele oye dun maroosa
Iji olele oye dun ma r'oyo ile
Kawa we ni o lo'ba ju ra won lo
Koledoye alugbo mo mo Ile awon baba eyin
Omo oloke meerindinlogun ti n be nile yin oo
Oke merin aduro bo
Oke merin abere bo
Merin akunlebo
Merin toku, ni oye ti n jade
Le fin she oye
Le fin sho oru
Iji alugbo omo ekun to t'oyo ile wa
Oye ki i pa ara igbeti
Eni abi so'ye
L'oye n pa
Oye ki i pa ara igbeti
Aso nla nla ni baba yin mu bo'ra o
Nle alugbo
Nle alugbo
Nle alugbo omo ekun
To t'oyo ile waaa
Folajuwon, omo ekun na da
Omo ekun na re
Ololade omo ekun na da
Omo ekun na re
Omo ekun na da
Omo ekun na re
Oko nana omo ekun na da
Omo ekun na re
Omo ekun na da
Omo ekun na re
Baba folarin omo ekun na da
Omo ekun na reeee

